Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 9:17-26 BIBELI MIMỌ (BM)

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;

18. kí wọ́n wá kíá,kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò.

19. Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!Ìtìjú ńlá dé bá wa,a níláti kó jáde nílé,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ”

20. Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò.

21. Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,ó ti wọ ààfin wa.Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.”

22. Sọ wí pé,“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

23. OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀,kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀;kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

24. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu,ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òyeati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́,tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé;nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”

25. Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà,

26. àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.”

Ka pipe ipin Jeremaya 9