Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 8:3-18 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

4. OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé,“Ṣé bí eniyan bá ṣubúkì í tún dìde mọ́?Àbí bí eniyan bá ṣìnà,kì í pada mọ́?

5. Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipadakúrò lọ́dọ̀ mi,tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn?Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́;wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.

6. Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.

7. Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀;wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.

8. Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé,‘Ọlọ́gbọ́n ni wá,a sì mọ òfin OLUWA?’Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké.

9. Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n:ìdààmú yóo bá wọn,ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀,ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?

10. Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn,n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn.Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù,títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù.Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.

11. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná,wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia.

12. Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́nnígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?Rárá o, ojú kì í tì wọ́n,nítorí pé wọn kò lójútì.Nítorí náà àwọn náà óo ṣubúnígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,a óo bì wọ́n ṣubúnígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

13. “Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà,igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí,àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ,ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

14. Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé,“Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀?Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ,kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi,kí á sì parun sibẹ;nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́,ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu,nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́.

15. À ń retí alaafia,ṣugbọn ire kankan kò dé.Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,ṣugbọn ìpayà ni a rí.

16. Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.”

17. OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;wọn yóo sì bù yín jẹ.”

18. Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,àárẹ̀ mú ọkàn mi.

Ka pipe ipin Jeremaya 8