Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 51:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní,“Wò ó! N óo gbé ẹ̀mí apanirun kan dìde sí Babiloni,ati sí àwọn ará Kalidea;

2. n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni,ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkàyóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú.

3. Kí tafàtafà má kẹ́ ọrun rẹ̀,kí ó má sì gbé ẹ̀wù irin rẹ̀ wọ̀.Má ṣe dá àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ sí,pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run patapata.

4. Kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n sì kú ní ilẹ̀ Kalidea,kí wọ́n gún wọn ní àgúnyọ láàrin ìgboro.

5. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀;ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.

6. Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni,kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀!Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni;nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí,yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni.

7. Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA,ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí;àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

Ka pipe ipin Jeremaya 51