Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 50:40-46 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ.

41. “Wò ó! Àwọn kan ń bọ̀ láti ìhà àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá, ati ọpọlọpọ ọba,wọ́n ń gbára wọn jọ láti máa bọ̀ láti òkèèrè.

42. Wọ́n kó ọrun ati ọ̀kọ̀ lọ́wọ́,ìkà ni wọ́n, wọn kò ní ojú àánú.Ìró wọn dàbí ìró rírú omi òkun;wọ́n gun ẹṣin,wọ́n tò bí àwọn ọmọ ogun.Wọ́n ń bọ̀ wá dojú kọ ọ́, ìwọ Babiloni!

43. Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn,ọwọ́ rẹ̀ rọ,ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí.

44. “Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

45. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn.

46. Ariwo wíwó odi Babiloni yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.”

Ka pipe ipin Jeremaya 50