Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 50:27-41 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ẹ pa gbogbo akọ mààlúù rẹ̀,ẹ fà wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran.Àwọn ará Babiloni gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti pé,àní ọjọ́ ìjìyà wọn.”

28. (Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.)

29. “Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli.

30. Nítorí náà àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, yóo kú ní gbàgede rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní a óo parun ní ọjọ́ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31. “Wò ó! Mo dojú kọ ọ́,ìwọ onigbeeraga yìí,nítorí pé ọjọ́ ti pé tí n óo jẹ ọ́ níyà.Èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

32. Agbéraga, o óo fẹsẹ̀ kọ, o óo sì ṣubú,kò ní sí ẹni tí yóo gbé ọ dìde.N óo dá iná kan ninu àwọn ìlú rẹ,iná náà yóo sì jó gbogbo àyíká rẹ.”

33. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “À ń ni àwọn ọmọ Israẹli lára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Juda; gbogbo àwọn tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn ni wọ́n wo ọwọ́ mọ́ wọn, wọn kò jẹ́ kí wọn lọ.

34. Ṣugbọn alágbára ni Olùràpadà wọn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, yóo jà fún wọn, kí ó lè fún ayé ní ìsinmi, ṣugbọn kí ìdààmú lè bá àwọn ará Babiloni.”

35. OLUWA ní,“Idà ni yóo pa àwọn ará Kalidea,idà ni yóo pa àwọn ará Babiloni,ati àwọn ìjòyè wọn,ati àwọn amòye wọn!

36. Idà ni yóo pa àwọn awoṣẹ́ wọn,kí wọ́n lè di òpè!Idà ni yóo pa àwọn ọmọ ogun wọn,kí wọ́n lè parẹ́!

37. Idà ni yóo pa àwọn ẹṣin wọn,ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn,idà ni yóo pa gbogbo àwọn àjèjì ọmọ ogun tí wọ́n wà láàrin wọn,Kí wọ́n lè di obinrin!Idà ni yóo fọ́ àwọn ilé ìṣúra wọn,kí wọ́n lè di ìkógun!

38. Ọ̀dá yóo dá ní ilẹ̀ wọn,kí àwọn odò wọn lè gbẹ!Nítorí pé ilẹ̀ tí ó kún fún ère ni,wọ́n sì kúndùn ìbọ̀rìṣà.

39. “Nítorí náà àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò ni yóo máa gbé inú Babiloni, ẹyẹ ògòǹgò yóo máa gbé inú rẹ̀. Kò ní sí eniyan níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ títí lae.

40. Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ.

41. “Wò ó! Àwọn kan ń bọ̀ láti ìhà àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá, ati ọpọlọpọ ọba,wọ́n ń gbára wọn jọ láti máa bọ̀ láti òkèèrè.

Ka pipe ipin Jeremaya 50