Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 50:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá wolii Jeremaya sọ̀rọ̀ nípa Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea pé:

2. “Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ta àsíá, kí o sì kéde.Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé,‘Ogun tí kó Babiloni,ojú ti oriṣa Bẹli,oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú.Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’

3. “Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í,yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́,ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀.

4. “Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda, yóo jọ wá pẹlu ẹkún, wọn yóo máa wá OLUWA Ọlọrun wọn.

5. Wọn yóo bèèrè ọ̀nà Sioni, wọn yóo kọjú sibẹ, wọn yóo sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á darapọ̀ mọ́ OLUWA, kí á sì bá a dá majẹmu ayérayé, tí a kò ní gbàgbé mọ́ títí ayé.’

6. “Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn.

Ka pipe ipin Jeremaya 50