Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 49:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ará Amoni nìyí: Ó ní,“Ṣé Israẹli kò lọ́mọ ni?Tabi kò ní àrólé?Kí ló dé tí àwọn tí ń bọ Milikomu ṣe gba ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi,tí wọ́n sì fi àwọn ìlú Gadi ṣe ibùjókòó?

2. Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni;Raba yóo di òkítì àlàpà,a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀;Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú.

3. Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni,nítorí pé ìlú Ai ti parun!Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba!Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀,ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà!Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn,pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀.

4. Kí ló dé tí ò ń fọ́nnu nípa agbára rẹ,ipá rẹ ti pin, ìwọ olóríkunkun ọmọbinrinìwọ tí o gbójú lé ọrọ̀ rẹ,tí ò ń wí pé, ‘Ta ló lè dojú kọ mí?’

5. Wò ó! N óo kó ìpayà bá ọ,láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n yí ọ ká;èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Gbogbo yín ni yóo fọ́nká,tí olukuluku yóo sì yà sí ọ̀nà tirẹ̀,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó àwọn tí ń sá fún ogun jọ.

6. “Ṣugbọn lẹ́yìn náà, n óo dá ire àwọn ará Amoni pada.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

7. Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí: Ó ní,“Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni?Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́?Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni?

8. Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ.Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀!Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn.

9. Bí àwọn tí ń kórè èso àjàrà bá bẹ̀rẹ̀ sí kórè,ṣebí wọn a máa fi èso díẹ̀ díẹ̀ sílẹ̀?Bí àwọn olè bá wọlé lóru,ṣebí ìba ohun tí ó bá wù wọ́n ni wọn yóo kó?

10. Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò,Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba,wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́.Àwọn ọmọ wọn ti parun,pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn;àwọn pàápàá sì ti di àwátì.

11. Fi àwọn ọmọ rẹ, aláìníbaba sílẹ̀,n óo pa wọ́n mọ́ láàyè,sì jẹ́ kí àwọn opó rẹ gbẹ́kẹ̀lé mi.

12. “Bí àwọn tí kò yẹ kí wọ́n jìyà bá jìyà, ṣé ìwọ wá lè lọ láìjìyà? O kò ní lọ láìjìyà, dájúdájú ìyà óo jẹ ọ́.

13. Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.”

14. Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n ní kí wọn kéde pé,“OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu,ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í!

15. Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeréláàrin àwọn orílẹ̀-èdè,o óo sì di yẹpẹrẹ,láàrin àwọn ọmọ eniyan.

16. Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta,tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé.Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì,n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Jeremaya 49