Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 48:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé,“Nebo gbé nítorí yóo di ahoro!Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o;ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀;

2. ògo Moabu ti dópin!Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni,wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu;ogun yóo máa le yín kiri.

3. Gbọ́ igbe kan ní Horonaimu,igbe ìsọdahoro ati ìparun ńlá!

4. “Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀.

5. Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún,nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu,ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé,

6. ‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín!Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’

7. “Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ.Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀.

8. Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ;àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.”

Ka pipe ipin Jeremaya 48