Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 47:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6. Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’

7. Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe?OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.”

Ka pipe ipin Jeremaya 47