Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 46:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ọba, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,fi ara rẹ̀ búra pé, bí òkè Tabori ti rí láàrin àwọn òkè,ati bí òkè Kamẹli létí òkun,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tí yóo yọ si yín yóo rí.

19. Ẹ di ẹrù yín láti lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀yin ará Ijipti!Nítorí pé Memfisi yóo di òkítì àlàpà,yóo di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo máa gbé ibẹ̀.

20. Ijipti dàbí ọmọ mààlúù tí ó lẹ́wà,ṣugbọn irù kan, tí ó ti ìhà àríwá fò wá, ti bà lé e.

21. Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀,dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀;àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ,wọn kò lè dúró;nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn,ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé.

22. Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ;nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára,wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a,bí àwọn tí wọn ń gé igi.

23. Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.

24. A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

25. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

Ka pipe ipin Jeremaya 46