Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 43:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Jeremaya parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn rán an sí gbogbo àwọn ará ìlú,

2. Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn ọkunrin aláfojúdi kan wí fún Jeremaya pé, “Irọ́ ni ò ń pa. OLUWA Ọlọrun wa kò rán ọ láti sọ fún wa pé kí á má lọ ṣe àtìpó ní Ijipti.

3. Baruku, ọmọ Neraya, ni ó fẹ́ mú wa kọlù ọ́, kí o lè fà wá lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá; tabi kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.”

4. Nítorí náà Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun ati gbogbo àwọn ará ìlú kò gba ohun tí OLUWA sọ, pé kí wọ́n dúró ní ilẹ̀ Juda.

5. Kàkà bẹ́ẹ̀, Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun kó gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọ́n pada wá sí ilẹ̀ Juda láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sálọ:

6. àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àwọn ọmọde, àwọn ìjòyè, ati gbogbo àwọn tí Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, fi sábẹ́ àkóso Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremaya wolii ati Baruku ọmọ Neraya.

7. Wọ́n kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n lọ títí tí wọ́n fi dé Tapanhesi.

8. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní Tapanhesi:

Ka pipe ipin Jeremaya 43