Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 42:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. “Bí ẹ bá wí pé ẹ kò ní dúró ní ilẹ̀ yìí, tí ẹ kò sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu;

14. bí ẹ bá ń wí pé, ‘Rárá o, a óo sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a kò ti ní gbúròó ogun tabi fèrè ogun, níbi tí ebi kò ti ní pa wá, a óo sì máa gbé ibẹ̀,’

15. ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí ẹ bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti, pé ẹ óo lọ máa gbé ibẹ̀, ogun tí ẹ̀ ń sá fún yóo bá yín níbẹ̀;

16. ìyàn tí ẹ̀ ń bẹ̀rù yóo tẹ̀lé yín lọ sí Ijipti; ebi tí ẹ páyà rẹ̀ yóo gbá tẹ̀lé yín, ibẹ̀ ni ẹ óo sì kú sí.

17. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti láti máa gbé ibẹ̀ yóo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, wọn kò ní ṣẹ́kù, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni wọn kò ní bọ́ ninu ibi tí n óo mú wá sórí wọn.’

18. “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí mo ti bínú sí àwọn ará Jerusalẹmu, tí inú mi sì ń ru sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n óo bínú si yín nígbà tí ẹ bá dé Ijipti. Ẹ óo di ẹni ègún, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ẹ̀gàn ati ẹni ẹ̀sín. Ẹ kò sì ní fojú kan ilẹ̀ yìí mọ́.’

19. “OLUWA ti sọ fún ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda pé kí ẹ má lọ sí Ijipti. Ẹ mọ̀ dájúdájú pé mo kìlọ̀ fun yín lónìí

20. pé ẹ ti fi ẹ̀mí ara yín wéwu nítorí ìṣìnà yín. Nítorí pé nígbà tí ẹ rán mi sí OLUWA Ọlọrun yín pé kí n gbadura fun yín, gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín bá wí ni kí n sọ fun yín, ẹ ní ẹ óo sì ṣe é.

21. Mo ti sọ ohun tí Ọlọrun wí fun yín lónìí, ṣugbọn ẹ kò tẹ̀lé ọ̀kan kan ninu ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ní kí n sọ fun yín.

22. Nítorí náà ẹ mọ̀ dájú pé ẹ óo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, ní ibi tí ẹ fẹ́ lọ máa gbé.”

Ka pipe ipin Jeremaya 42