Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 41:3-9 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Iṣimaeli pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà pẹlu Gedalaya ní Misipa, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà níbẹ̀.

4. Ọjọ́ keji tí wọ́n pa Gedalaya tán, kí ẹnikẹ́ni tó gbọ́ nípa rẹ̀,

5. àwọn ọgọrin eniyan kan wá láti Ṣekemu, Ṣilo ati láti Samaria pẹlu irùngbọ̀n wọn ní fífá, wọ́n fa agbádá wọn ya, wọ́n sì ṣá ara wọn lọ́gbẹ́. Wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ati turari lọ́wọ́ wá sí Tẹmpili OLUWA.

6. Iṣimaeli, ọmọ Netanaya sọkún pàdé wọn láti Misipa. Bí ó ti pàdé wọn ó wí pé, “Ẹ máa kálọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu.”

7. Nígbà tí wọ́n wọ ààrin ìlú, Iṣimaeli ọmọ Netanaya ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì kó òkú wọn dà sí inú kòtò.

8. Ṣugbọn àwọn mẹ́wàá kan ninu wọn sọ fún Iṣimaeli pé, “Má pa wá, nítorí a ní ọkà wíítì, ọkà baali, ati òróró ati oyin ní ìpamọ́ ninu oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n bí ó ti pa àwọn yòókù wọn.

9. Kòtò tí Iṣimaeli ju òkú àwọn eniyan tí ó pa sí ni kòtò tí ọba Asa gbẹ́ tí ó fi dí ọ̀nà mọ́ Baaṣa ọba Israẹli; ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya fi òkú eniyan tí ó pa kún kòtò náà.

Ka pipe ipin Jeremaya 41