Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 38:8-24 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ebedimeleki jáde ní ààfin, ó lọ bá ọba ó sì wí fún un pé,

9. “Kabiyesi, oluwa mi, gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan wọnyi ṣe sí wolii Jeremaya kò dára. Inú kànga ni wọ́n jù ú sí, ebi ni yóo sì pa á sibẹ nítorí pé kò sí burẹdi ní ìlú mọ́.”

10. Ọba bá pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Etiopia, ó ní, “Mú eniyan mẹta lọ́wọ́, kí ẹ lọ yọ Jeremaya wolii kúrò ninu kànga náà kí ó tó kú.”

11. Ebedimeleki bá mú àwọn ọkunrin mẹta náà, wọ́n lọ sí yàrá kan ní ilé ìṣúra tí ó wà láàfin ọba. Ó mú àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó níbẹ̀, ó so okùn mọ́ wọn, ó sì nà án sí Jeremaya ninu kànga.

12. Ó bá sọ fún Jeremaya pé kí ó fi àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó náà sí abíyá mejeeji, kí ó fi okùn kọ́ ara rẹ̀ lábíyá. Jeremaya sì ṣe bẹ́ẹ̀.

13. Wọ́n bá fi okùn fa Jeremaya jáde kúrò ninu kànga. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin.

14. Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú Jeremaya wolii wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà kẹta tí ó wà ní Tẹmpili OLUWA, ó wí fún Jeremaya pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì fi ohunkohun pamọ́ fún mi.”

15. Jeremaya bá wí fún Sedekaya, ó ní, “Bí mo bá sọ fún ọ, o kò ní pa mí dájúdájú? Bí mo bá sì fún ọ ní ìmọ̀ràn, o kò ní gbà.”

16. Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.”

17. Jeremaya bá wí fún Sedekaya pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọn ó dá ẹ̀mí rẹ sí, wọn kò sì ní dáná sun ìlú yìí, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ yóo sì yè.

18. Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.”

19. Sedekaya ọba bá wí fún Jeremaya pé, “Ẹ̀rù àwọn ará Juda tí wọ́n sá lọ bá àwọn ará Kalidea ń bà mí. Wọ́n lè fà mí lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.”

20. Jeremaya dáhùn pé, “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Tẹ̀lé ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń sọ fún ọ; yóo dára fún ọ, a óo sì dá ẹ̀mí rẹ sí.

21. Ṣugbọn bí o bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ ohun tí OLUWA fihàn mí nìyí:

22. Wò ó, mo rí i tí wọn ń kó àwọn obinrin tí wọ́n wà ní ààfin ọba Juda jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n sì ń wí pé,‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o fọkàn tán tàn ọ́,wọ́n sì ti ṣẹgun rẹ;nisinsinyii tí o rì sinu ẹrẹ̀,wọ́n pada lẹ́yìn rẹ.’

23. “Gbogbo àwọn aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóo kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea, ìwọ gan-an kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ọwọ́ ọba Babiloni yóo tẹ̀ ọ́, wọn yóo sì dáná sun ìlú yìí.”

24. Sedekaya ọba bá kìlọ̀ fún Jeremaya pé, “Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ gbogbo nǹkan tí a jọ sọ, o kò sì ní kú.

Ka pipe ipin Jeremaya 38