Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 38:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ọba bá pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Etiopia, ó ní, “Mú eniyan mẹta lọ́wọ́, kí ẹ lọ yọ Jeremaya wolii kúrò ninu kànga náà kí ó tó kú.”

11. Ebedimeleki bá mú àwọn ọkunrin mẹta náà, wọ́n lọ sí yàrá kan ní ilé ìṣúra tí ó wà láàfin ọba. Ó mú àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó níbẹ̀, ó so okùn mọ́ wọn, ó sì nà án sí Jeremaya ninu kànga.

12. Ó bá sọ fún Jeremaya pé kí ó fi àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó náà sí abíyá mejeeji, kí ó fi okùn kọ́ ara rẹ̀ lábíyá. Jeremaya sì ṣe bẹ́ẹ̀.

13. Wọ́n bá fi okùn fa Jeremaya jáde kúrò ninu kànga. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin.

14. Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú Jeremaya wolii wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà kẹta tí ó wà ní Tẹmpili OLUWA, ó wí fún Jeremaya pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì fi ohunkohun pamọ́ fún mi.”

15. Jeremaya bá wí fún Sedekaya, ó ní, “Bí mo bá sọ fún ọ, o kò ní pa mí dájúdájú? Bí mo bá sì fún ọ ní ìmọ̀ràn, o kò ní gbà.”

16. Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.”

17. Jeremaya bá wí fún Sedekaya pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọn ó dá ẹ̀mí rẹ sí, wọn kò sì ní dáná sun ìlú yìí, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ yóo sì yè.

18. Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.”

Ka pipe ipin Jeremaya 38