Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 38:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Ṣefataya, ọmọ Matani, ati Gedalaya, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Paṣuri ọmọ Malikaya gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé,

2. “OLUWA ní, ẹni tí ó bá dúró ní ìlú Jerusalẹmu yóo kú ikú idà, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn; ṣugbọn àwọn tí wọn bá jáde tọ àwọn ará Kalidea lọ yóo yè. Ó ní ọ̀rọ̀ wọn yóo dàbí ẹni tí ó ja àjàbọ́, ṣugbọn yóo wà láàyè.

3. Ati pé dájúdájú, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Babiloni, wọn yóo sì gbà á.”

4. Àwọn ìjòyè náà bá sọ fún ọba pé, “Ẹ jẹ́ kí á pa ọkunrin yìí nítorí pé ó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tí wọn kù láàrin ìlú, ati gbogbo àwọn eniyan nítorí irú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún wọn. Ọkunrin yìí kò fẹ́ alaafia àwọn eniyan wọnyi, àfi ìpalára wọn.”

5. Sedekaya ọba bá dá wọn lóhùn, pé, “Ìkáwọ́ yín ló wà, n kò jẹ́ ṣe ohunkohun tí ó bá lòdì sí ìfẹ́ yín.”

6. Wọ́n bá mú Jeremaya, wọ́n jù ú sinu kànga Malikaya, ọmọ ọba, tí ó wà ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n fi okùn sọ Jeremaya kalẹ̀ sinu kànga náà, kò sí omi ninu rẹ̀, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremaya sì rì sinu ẹrẹ̀ náà.

7. Nígbà tí Ebedimeleki ará Etiopia tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremaya sinu kànga. Ọba wà níbi tí ó jókòó sí ní ibodè Bẹnjamini.

8. Ebedimeleki jáde ní ààfin, ó lọ bá ọba ó sì wí fún un pé,

Ka pipe ipin Jeremaya 38