Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 32:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹwaa tí Sedekaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kejidinlogun tí Nebukadinesari jọba.

2. Àwọn ọmọ ogun Babiloni dó ti Jerusalẹmu ní àkókò yìí, Jeremaya wolii sì wà ní ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sọ ọ́ sí, ní àgbàlá ààfin ọba Juda.

3. Sedekaya ọba Juda ni ó sọ Jeremaya sẹ́wọ̀n, ó ní, kí ló dé tí Jeremaya fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé OLUWA ní òun óo fi Jerusalẹmu lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á;

4. ati pé Sedekaya ọba Juda kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea. Ó ní Jeremaya sọ pé dájúdájú, OLUWA óo fi òun Sedekaya lé ọba Babiloni lọ́wọ́, àwọn yóo rí ara àwọn lojukooju, àwọn yóo sì bá ara àwọn sọ̀rọ̀.

5. Yóo mú òun Sedekaya lọ sí Babiloni, ibẹ̀ ni òun óo sì wà títí OLUWA yóo fi ṣe ẹ̀tọ́ fún òun. Ó ní bí àwọn tilẹ̀ bá àwọn ará Kalidea jagun, àwọn kò ní borí.

6. Jeremaya ní, “OLUWA sọ fún mi pé,

7. ‘Hanameli ọmọ Ṣalumu, arakunrin baba rẹ, yóo wá bá ọ pé kí o ra oko òun tí ó wà ní Anatoti, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada.’

8. Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.

9. Mo bá ra oko náà lọ́wọ́ Hanameli ọmọ arakunrin baba mi, mo sì wọn fadaka ṣekeli mẹtadinlogun fún un.

10. Mo kọ ọ́ sinu ìwé, mo fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́, mo pe àwọn eniyan láti ṣe ẹlẹ́rìí; mo sì fi òṣùnwọ̀n wọn fadaka náà.

Ka pipe ipin Jeremaya 32