Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 31:29-37 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé,‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan,àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’

30. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan,òun ni eyín yóo kan.Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.

31. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun.

32. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn.

33. Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi.

34. Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

35. OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán,tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́,tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya,òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

36. Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun,ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae.

37. Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run,tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé,ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò,nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe.

Ka pipe ipin Jeremaya 31