Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 20:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Paṣuri alufaa, ọmọ Imeri, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ ilé OLUWA, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ,

2. ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA.

3. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí Paṣuri tú Jeremaya sílẹ̀ ninu ààbà, Jeremaya wí fún un pé, “Kì í ṣe Paṣuri ni OLUWA pe orúkọ rẹ, ìpayà lọ́tùn-ún ati lósì ni OLUWA pè ọ́.

4. OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n.

5. Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni.

6. Ní ti ìwọ Paṣuri, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ, wọn óo ko yín ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí, ibẹ̀ ni wọ́n óo sì sin yín sí; àtìwọ, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ò ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.’ ”

7. OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn;o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi.Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́,gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.

8. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé,“Ogun ati ìparun dé!”Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.

Ka pipe ipin Jeremaya 20