Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 2:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí,àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi,àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali,wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn.

9. “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́,n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.”OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

10. Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká,tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní,bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí.

11. Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́?Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn,wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀.

12. Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run,kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.”

13. OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji:wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀,wọ́n ṣe kànga fún ara wọn;kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.

14. “Ṣé ẹrú ni Israẹli ni,àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé?Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15. Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn,wọ́n bú ramúramù.Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro.Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀,láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn.

16. Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀.

17. Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín,nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀,nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà?

Ka pipe ipin Jeremaya 2