Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 16:19-21 BIBELI MIMỌ (BM)

19. OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi,ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ,láti gbogbo òpin ayé,wọn yóo máa wí pé:“Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún,ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan.

20. Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun?Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.”

21. OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀;àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi;wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Jeremaya 16