Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 14:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run.

16. Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.”

17. OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé,‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru,kí ó má dáwọ́ dúró,nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi.

18. Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko,àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀!Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú,àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀.Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà,wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ”

19. OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni?Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ?Kí ló dé tí o fi lù wá,tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn?À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé.À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí.

20. OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa,ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa,nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.

21. Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ,má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo.Ranti majẹmu tí o bá wa dá,ranti, má sì ṣe dà á.

22. Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn,ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀?Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò?OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni?Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé,nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.

Ka pipe ipin Jeremaya 14