Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 13:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.”

12. OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’

13. Ìwọ wá wí fún wọn pé, èmi OLUWA ní n óo rọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí ní ọtí àrọyó, ati àwọn ọba tí wọn jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

14. N óo máa sọ wọ́n lu ara wọn. Baba ati ọmọ yóo máa kọlu ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní ṣàánú wọn, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yọ́nú sí wọn débi pé kí n má fẹ́ pa wọ́n run.”

15. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́,ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀.

16. Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú.Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè,níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀.Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀,yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu,yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri.

17. Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́,ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín.N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,omi yóo sì máa dà lójú mi,nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn.

18. Wí fún ọba ati ìyá ọba pé,“Ẹ sọ̀kalẹ̀ lórí ìtẹ́ yín,nítorí adé yín tí ó lẹ́wà ti ṣí bọ́ sílẹ̀ lórí yín.”

Ka pipe ipin Jeremaya 13