Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 12:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá,nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà;ẹnikẹ́ni kò ní alaafia,

13. Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè.Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan.Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè,nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.”

14. Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn.

15. Lẹ́yìn tí mo bá kó wọn kúrò tán, n óo pada ṣàánú wọn, n óo dá olukuluku pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

16. Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi.

17. Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe àìgbọràn, n óo yọ ọ́ kúrò patapata, n óo sì pa á run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 12