Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 11:18-23 BIBELI MIMỌ (BM)

18. OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi.

19. Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20. Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó ń dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21. Nítorí náà, OLUWA sọ nípa àwọn ará Anatoti, tí wọn ń wá ẹ̀mí Jeremaya, tí wọn sì ń sọ fún un pé, “O kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ni a óo pa ọ́.”

22. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní òun óo jẹ wọ́n níyà; àwọn ọdọmọkunrin wọn yóo kú lójú ogun, ìyàn ni yóo sì pa àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.

23. Kò ní sí ẹni tí yóo ṣẹ́kù nítorí pé òun óo mú kí ibi dé bá àwọn ará Anatoti, nígbà tí àkókò bá tó tí òun óo jẹ wọ́n níyà.

Ka pipe ipin Jeremaya 11