Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 11:16-20 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná.

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.”

18. OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi.

19. Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20. Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó ń dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Jeremaya 11