Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 11:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀,

2. ó ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí o sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ Juda, ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

3. Sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ majẹmu

4. tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín.

5. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óo mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé n óo fún wọn ní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin,’ bí ó ti rí ní òní.”Mo bá dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA.”

6. OLUWA tún sọ fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda ati ní àwọn òpópó Jerusalẹmu, pé kí wọn fetí sí ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí wọ́n sì ṣe bí ó ti wí.

7. Mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, títí tí ó sì fi di òní, n kò yé kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn èmi OLUWA.

8. Sibẹsibẹ wọn kò gbọ́; wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, olukuluku ń ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ majẹmu yìí ṣẹ mọ́ wọn lára, bí mo ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọn ṣe, ṣugbọn tí wọn kò ṣe.”

9. OLUWA tún wí fún mi pé, “Àwọn ọmọ Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ń dìtẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 11