Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 9:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ti òun ti ẹ̀jẹ̀, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ìyè wà.

5. Dájúdájú n óo gbẹ̀san lára ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, kì báà jẹ́ ẹranko ni ó paniyan tabi eniyan ni ó pa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan.

7. “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.”

8. Lẹ́yìn náà Ọlọrun sọ fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé,

9. “Wò ó! Mo bá ẹ̀yin ati atọmọdọmọ yín dá majẹmu, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà pẹlu yín:

10. Gbogbo àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko tí wọ́n bá yín jáde ninu ọkọ̀,

11. majẹmu náà ni pé, lae, n kò tún ní fi ìkún omi pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìkún omi tí yóo pa ayé rẹ́ mọ́.

12. Ohun tí yóo jẹ́ àmì majẹmu tí mo ń bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá, tí yóo sì wà fún atọmọdọmọ yín ní ọjọ́ iwájú nìyí:

13. mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, òun ni yóo máa jẹ́ àmì majẹmu tí mo bá ayé dá.

14. Nígbàkúùgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú ní ojú ọ̀run, tí òṣùmàrè bá sì yọ jáde,

15. n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́.

16. Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.

17. Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.”

18. Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 9