Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 35:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún Jakọbu pé, “Dìde, lọ sí Bẹtẹli kí o máa gbé ibẹ̀, kí o tẹ́ pẹpẹ kan fún Ọlọrun tí ó farahàn ọ́ nígbà tí ò ń sálọ fún Esau, arakunrin rẹ.”

2. Jakọbu bá sọ fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ ati àwọn alábàágbé rẹ̀, pé, “Ẹ kó gbogbo ère oriṣa tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín dànù, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.

3. Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtẹli, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún Ọlọrun, ẹni tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, tí ó sì wà pẹlu mi ní gbogbo ibi tí mo ti lọ.”

4. Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu.

5. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.

6. Jakọbu ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá wá sí Lusi, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí nnì ni Bẹtẹli.

7. Ó tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ, ó sì sọ ibẹ̀ ní Eli-Bẹtẹli, nítorí pé níbẹ̀ ni Ọlọrun ti farahàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arakunrin rẹ̀.

8. Níbẹ̀ ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú sí, wọ́n sì sin ín sí abẹ́ igi oaku kan ní ìhà gúsù Bẹtẹli, Jakọbu bá sọ ibẹ̀ ní Aloni-bakuti.

9. Ọlọrun tún fara han Jakọbu, nígbà tí ó jáde kúrò ní Padani-aramu, ó súre fún un.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 35