Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 32:3-20 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Jakọbu rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Esau, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Seiri, ní agbègbè Edomu.

4. Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí ẹ óo sọ fún Esau, oluwa mi nìyí, ẹ ní èmi, Jakọbu iranṣẹ rẹ̀, ní kí ẹ sọ fún un pé mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani, ati pé ibẹ̀ ni mo sì ti wà títí di àkókò yìí.

5. Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.”

6. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà pada wá jábọ̀ fún Jakọbu, wọ́n sọ fún un pé, “A jíṣẹ́ rẹ fún Esau arakunrin rẹ, ó sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ pẹlu irinwo (400) ọkunrin.”

7. Ẹ̀rù ba Jakọbu gidigidi, ó sì dààmú, ó bá dá àwọn eniyan tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ati agbo mààlúù, ati agbo aguntan ati àwọn ràkúnmí rẹ̀ sí ọ̀nà meji meji.

8. Ó rò ninu ara rẹ̀ pé bí Esau bá dé ọ̀dọ̀ ìpín tí ó wà níwájú, tí ó bá sì pa wọ́n run, ìpín kan tí ó kù yóo sá àsálà.

9. Jakọbu bá gbadura báyìí pé, “Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, Ọlọrun tí ó wí fún mi pé, ‘Pada sí ilẹ̀ rẹ ati sí ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, n óo sì ṣe ọ́ níre.’

10. N kò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí tí ó kéré jùlọ ninu ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀, ati òdodo tí o ti fihan èmi iranṣẹ rẹ, nítorí ọ̀pá lásán ni mo mú lọ́wọ́ nígbà tí mo gòkè odò Jọdani, ṣugbọn nisinsinyii, mo ti di ẹgbẹ́ ogun ńlá meji.

11. Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn.

12. Ìwọ ni o ṣá sọ fún mi pé, ‘Ire ni n óo ṣe fún ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí iyanrìn etí òkun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè kà tán.’ ”

13. Ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì mú ninu ohun ìní rẹ̀ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún Esau arakunrin rẹ̀.

14. Ó ṣa igba (200) ewúrẹ́ ati ogún òbúkọ, igba (200) aguntan, ati ogún àgbò,

15. ọgbọ̀n abo ràkúnmí, tàwọn tọmọ wọn, ogoji abo mààlúù ati akọ mààlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati akọ mẹ́wàá.

16. Ó fi iranṣẹ kọ̀ọ̀kan ṣe olùtọ́jú agbo ẹran kọ̀ọ̀kan. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ wọnyi pé, “Ẹ máa lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin agbo ẹran kan ati ekeji.”

17. Ó sọ fún èyí tí ó ṣáájú patapata pé, “Nígbà tí Esau arakunrin mi bá pàdé rẹ, tí ó sì bi ọ́ pé, ‘Ti ta ni ìwọ í ṣe? Níbo ni ò ń lọ? Ta ló sì ni àwọn ẹran tí wọ́n wà níwájú rẹ?’

18. Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ”

19. Bákan náà ni ó kọ́ ekeji ati ẹkẹta ati gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n tẹ̀lé àwọn agbo ẹran náà. Ó ní, “Nǹkan kan náà ni kí ẹ máa wí fún Esau, nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀.

20. Kí ẹ sì wí pé, ‘Jakọbu alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, bóyá òun lè fi àwọn ẹ̀bùn tí ó tì ṣáájú wọnyi tù ú lójú, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ojú àwọn mejeeji bá pàdé, bóyá yóo dáríjì òun.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 32