Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 28:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Jakọbu kúrò ní Beeriṣeba, ó ń lọ sí Harani.

11. Nígbà tí ó dé ibìkan tí ó rí i pé ilẹ̀ ti ń ṣú, ó gbé ọ̀kan ninu àwọn òkúta tí ó wà níbẹ̀, ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.

12. Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò.

13. OLUWA pàápàá dúró lókè rẹ̀, ó wí fún un pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun Abrahamu baba rẹ ati Ọlọrun Isaaki, ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi fún.

14. Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé.

15. Wò ó, mo wà pẹlu rẹ, n óo pa ọ́ mọ́ níbikíbi tí o bá lọ, n óo sì mú ọ pada wá sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé n kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí tí n óo fi ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún ọ.”

16. Nígbà tí Jakọbu tají ní ojú oorun rẹ̀, ó ní, “Dájúdájú OLUWA ń bẹ níhìn-ín, n kò sì mọ̀!”

17. Ẹ̀rù bà á, ó sì wí pé, “Ààrin yìí mà tilẹ̀ bani lẹ́rù pupọ o! Ibí yìí kò lè jẹ́ ibòmíràn bíkòṣe ilé Ọlọrun, ibí gan-an ni ẹnu ibodè ọ̀run.”

18. Jakọbu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí nàró gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n, ó sì da òróró sórí rẹ̀.

19. Ó sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli, ṣugbọn Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí.

20. Jakọbu bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan, ó ní “Bí Ọlọrun bá wà pẹlu mi, bí ó bá sì pa mí mọ́ ní ọ̀nà ibi tí mò ń lọ yìí, tí ó bá fún mi ní oúnjẹ jẹ, tí ó sì fún mi ni aṣọ wọ̀,

21. tí mo bá sì pada dé ilé baba mi ní alaafia, OLUWA ni yóo máa jẹ́ Ọlọrun mi.

22. Òkúta tí mo sì gbé nàró bí ọ̀wọ̀n yìí yóo di ilé Ọlọrun, n óo sì fún ìwọ Ọlọrun ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí o bá fún mi.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 28