Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 24:26-38 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ọkunrin náà bá tẹríba, ó sì sin OLUWA,

27. ó sọ pé, “Ọpẹ́ ni fún ọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, tí kò gbàgbé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òdodo rẹ̀ sí oluwa mi. Ní tèmi, OLUWA ti tọ́ mi sọ́nà tààrà, sí ilé àwọn ìbátan oluwa mi.”

28. Ọmọbinrin náà bá sáré lọ sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀.

29. Rebeka ní arakunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Labani. Labani yìí ni ó sáré lọ bá ọkunrin náà ní ìdí kànga.

30. Lẹ́yìn tí ó rí òrùka ati ẹ̀gbà ọwọ́ lọ́wọ́ arabinrin rẹ̀, tí ó sì ti gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkunrin náà sọ fún òun, ó lọ bá ọkunrin náà níbi tí ó dúró sí lẹ́bàá kànga pẹlu àwọn ràkúnmí rẹ̀.

31. Labani sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé, ìwọ ẹni tí OLUWA bukun. Èéṣe tí o fi dúró níta gbangba? Mo ti tọ́jú ilé, mo sì ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún àwọn ràkúnmí rẹ.”

32. Ọkunrin náà bá wọlé, Labani sì tú gàárì àwọn ràkúnmí rẹ̀, ó fi koríko ati oúnjẹ fún wọn. Ó fún un ní omi láti fi ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá.

33. Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún un pé kí ó jẹ, ṣugbọn ó wí pé, “N kò ní jẹun títí n óo fi jíṣẹ́ tí wọ́n rán mi.” Labani dáhùn, ó ní, “À ń gbọ́.”

34. Ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Iranṣẹ Abrahamu ni mí,

35. OLUWA ti bukun oluwa mi lọpọlọpọ, ó sì ti di eniyan ńlá. OLUWA ti fún un ní ọpọlọpọ mààlúù ati agbo ẹran, ọpọlọpọ fadaka ati wúrà, ọpọlọpọ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ati ọpọlọpọ ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

36. Sara, aya oluwa mi bí ọmọkunrin kan fún un lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ọmọ yìí sì ni oluwa mi fi ohun gbogbo tí ó ní fún.

37. Oluwa mi mú mi búra pé n kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí òun ń gbé.

38. Ó ni mo gbọdọ̀ wá síhìn-ín, ní ilé baba òun ati sọ́dọ̀ àwọn ẹbí òun láti fẹ́ aya fún ọmọ òun.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 24