Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 23:9-16 BIBELI MIMỌ (BM)

9. kí ó fún mi ní ihò Makipela, òun ni ó ni ihò náà, ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ̀ ni ó wà. Títà ni mo fẹ́ kí ó tà á fún mi ní iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó, lójú gbogbo yín, n óo sì lè máa lo ilẹ̀ náà bí itẹ́ òkú.”

10. Efuroni alára wà ní ìjókòó pẹlu àwọn ará Hiti yòókù, lójú gbogbo àwọn ará ìlú náà ni ó ti dá Abrahamu lóhùn, ó ní,

11. “Rárá o! oluwa mi, gbọ́, mo fún ọ ní ilẹ̀ náà, ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀, lójú gbogbo àwọn eniyan mi ni mo sì ti fún ọ, lọ sin aya rẹ sibẹ.”

12. Nígbà náà ni Abrahamu tẹríba níwájú gbogbo wọn.

13. Ó bá sọ fún Efuroni lójú gbogbo wọn, ó ní, “Ṣugbọn, bí ó bá ti ọkàn rẹ wá, fún mi ní ilẹ̀ náà, kí n sì san owó rẹ̀ fún ọ. Gbà á lọ́wọ́ mi, kí n lè lọ sin aya mi sibẹ.”

14. Efuroni dá Abrahamu lóhùn, ó ní,

15. “Olúwa mi, gbọ́, ilẹ̀ yìí kò ju irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ, èyí kò tó nǹkankan láàrin èmi pẹlu rẹ. Lọ sin òkú aya rẹ.”

16. Abrahamu gbà bí Efuroni ti wí, ó bá wọn irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka tí Efuroni dárúkọ fún un lójú gbogbo wọn, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò ìgbà náà ń lò.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 23