Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 23:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó kú ní Kiriati Ariba, ní Heburoni, ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu sọkún, ó sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

3. Nígbà tí ó yá, Abrahamu dìde níwájú òkú Sara, ó lọ bá àwọn ará Hiti, ó ní,

4. “Àlejò ni mo jẹ́ láàrin yín, ẹ bá mi wá ilẹ̀ ní ìwọ̀nba ninu ilẹ̀ yín tí mo lè máa lò bí itẹ́ òkú, kí n lè sin òkú aya mi yìí, kí ó kúrò nílẹ̀.”

5. Àwọn ará Hiti dá Abrahamu lóhùn, wọ́n ní,

6. “Gbọ́, oluwa wa, olóyè pataki ni o jẹ́ láàrin wa. Sin òkú aya rẹ síbikíbi tí ó bá wù ọ́ jùlọ ninu àwọn itẹ́ òkú wa, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wa tí kò ní fún ọ ní itẹ́ òkú rẹ̀, tabi tí yóo dí ọ lọ́wọ́, pé kí o má ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe.”

7. Abrahamu bá dìde, ó tẹríba níwájú wọn,

8. ó ní, “Bí ẹ bá fẹ́ kí n sin òkú aya mi kúrò nílẹ̀ nítòótọ́, ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì bá mi sọ fún Efuroni ọmọ Sohari,

9. kí ó fún mi ní ihò Makipela, òun ni ó ni ihò náà, ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ̀ ni ó wà. Títà ni mo fẹ́ kí ó tà á fún mi ní iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó, lójú gbogbo yín, n óo sì lè máa lo ilẹ̀ náà bí itẹ́ òkú.”

10. Efuroni alára wà ní ìjókòó pẹlu àwọn ará Hiti yòókù, lójú gbogbo àwọn ará ìlú náà ni ó ti dá Abrahamu lóhùn, ó ní,

11. “Rárá o! oluwa mi, gbọ́, mo fún ọ ní ilẹ̀ náà, ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀, lójú gbogbo àwọn eniyan mi ni mo sì ti fún ọ, lọ sin aya rẹ sibẹ.”

12. Nígbà náà ni Abrahamu tẹríba níwájú gbogbo wọn.

13. Ó bá sọ fún Efuroni lójú gbogbo wọn, ó ní, “Ṣugbọn, bí ó bá ti ọkàn rẹ wá, fún mi ní ilẹ̀ náà, kí n sì san owó rẹ̀ fún ọ. Gbà á lọ́wọ́ mi, kí n lè lọ sin aya mi sibẹ.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 23