Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 18:28-33 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.”

29. Ó tún bèèrè pé, “Bí a bá rí ogoji ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn, ó ní, “N kò ní pa á run nítorí ogoji eniyan náà.”

30. Ó bá tún wí pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, bí a bá rí ọgbọ̀n eniyan ńkọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí ọgbọ̀n olódodo, n kò ní pa ìlú náà run.”

31. Ó tún dáhùn pé “Jọ̀wọ́ dárí àfojúdi mi jì mí nítorí ọ̀rọ̀ mi, bí a bá rí ogún eniyan ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn pé, “Nítorí ti ogún eniyan, n kò ní pa á run.”

32. Abrahamu tún dáhùn pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí ni ó kù tí n óo sọ̀rọ̀. Bí a bá rí eniyan mẹ́wàá ńkọ́?”OLUWA tún dá a lóhùn pé, “N kò ní pa á run nítorí ti eniyan mẹ́wàá.”

33. Nígbà tí OLUWA bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó bá tirẹ̀ lọ, Abrahamu náà bá pada sí ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 18