Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 18:14-29 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.”

15. Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.”

16. Nígbà tí àwọn ọkunrin náà kúrò lọ́dọ̀ Abrahamu, wọ́n dojú kọ ọ̀nà Sodomu, Abrahamu bá wọn lọ láti sìn wọ́n dé ọ̀nà.

17. OLUWA sọ pé, “Mo ha gbọdọ̀ fi ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí pamọ́ fún Abrahamu,

18. nígbà tí ó jẹ́ pé ìran rẹ̀ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá tí yóo lágbára, ati pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè?

19. N kò ní fi pamọ́ fún un, nítorí pé mo ti yàn án, kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ará ilé rẹ̀, láti máa pa ìlànà èmi OLUWA mọ́, ati kí wọ́n sì jẹ́ olódodo ati olóòótọ́, kí èmi OLUWA lè mú ìlérí mi ṣẹ fún Abrahamu.”

20. OLUWA bá sọ pé; “Ẹ̀sùn tí àwọn eniyan fi ń kan Sodomu ati Gomora ti pọ̀ jù, ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jáì!

21. Mo fẹ́ lọ fi ojú ara mi rí i, kí n fi mọ̀, bóyá gbogbo bí mo ti ń gbọ́ nípa wọn ni wọ́n ń ṣe nítòótọ́.”

22. Àwọn ọkunrin náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà Sodomu lọ, ṣugbọn Abrahamu tún dúró níwájú OLUWA níbẹ̀.

23. Abrahamu bá súnmọ́ OLUWA, ó wí pé, “O ha gbọdọ̀ pa àwọn olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú bí?

24. A kì í bàá mọ̀, bí aadọta olódodo bá wà ninu ìlú náà, ṣé o óo pa ìlú náà run, o kò sì ní dá a sí nítorí aadọta olódodo tí ó wà ninu rẹ̀?

25. Kí á má rí i pé o ṣe irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀! Kí o pa olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú? Ṣé kò ní sí ìyàtọ̀ láàrin ìpín àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn olódodo ni? A kò gbọdọ̀ gbọ́ ọ. Ìwọ onídàájọ́ gbogbo ayé kò ha ní ṣe ẹ̀tọ́ bí?”

26. OLUWA dáhùn, ó ní, “Bí mo bá rí aadọta olódodo ninu ìlú Sodomu, n óo dá gbogbo ìlú náà sí nítorí tiwọn.”

27. Abrahamu tún sọ fún OLUWA pé, “Jọ̀wọ́, dárí àfojúdi mi jì mí, èmi eniyan lásán, nítorí n kò ní ẹ̀tọ́ láti bá ìwọ OLUWA jiyàn?

28. Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.”

29. Ó tún bèèrè pé, “Bí a bá rí ogoji ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn, ó ní, “N kò ní pa á run nítorí ogoji eniyan náà.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 18