Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 18:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn.

12. Nítorí náà, nígbà tí Sara gbọ́ pé òun óo bímọ, ó rẹ́rìn-ín sinu ara rẹ̀, ó ní, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó, tí ọkọ mi náà sì ti di arúgbó, ǹjẹ́ mo tilẹ̀ tún lè gbádùn oorun ọmọ bíbí?”

13. OLUWA bi Abrahamu pé, “Èéṣe tí Sara fi rẹ́rìn-ín, tí ó wí pé, ṣé lóòótọ́ ni òun óo bímọ lẹ́yìn tí òun ti darúgbó?

14. Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.”

15. Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.”

16. Nígbà tí àwọn ọkunrin náà kúrò lọ́dọ̀ Abrahamu, wọ́n dojú kọ ọ̀nà Sodomu, Abrahamu bá wọn lọ láti sìn wọ́n dé ọ̀nà.

17. OLUWA sọ pé, “Mo ha gbọdọ̀ fi ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí pamọ́ fún Abrahamu,

18. nígbà tí ó jẹ́ pé ìran rẹ̀ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá tí yóo lágbára, ati pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè?

19. N kò ní fi pamọ́ fún un, nítorí pé mo ti yàn án, kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ará ilé rẹ̀, láti máa pa ìlànà èmi OLUWA mọ́, ati kí wọ́n sì jẹ́ olódodo ati olóòótọ́, kí èmi OLUWA lè mú ìlérí mi ṣẹ fún Abrahamu.”

20. OLUWA bá sọ pé; “Ẹ̀sùn tí àwọn eniyan fi ń kan Sodomu ati Gomora ti pọ̀ jù, ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jáì!

21. Mo fẹ́ lọ fi ojú ara mi rí i, kí n fi mọ̀, bóyá gbogbo bí mo ti ń gbọ́ nípa wọn ni wọ́n ń ṣe nítòótọ́.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 18