Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 15:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó sọ fún un pé “Èmi ni OLUWA tí ó mú ọ jáde láti ìlú Uri, ní ilẹ̀ Kalidea, láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ ní ohun ìní.”

8. Ṣugbọn Abramu bèèrè pé, “OLUWA Ọlọrun, báwo ni n óo ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóo jẹ́ tèmi?”

9. OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “Mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù ọlọ́dún mẹta kan, ati ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹta kan, ati àgbò ọlọ́dún mẹta kan, ati àdàbà kan ati ọmọ ẹyẹlé kan wá.”

10. Ó kó gbogbo wọn wá fún OLUWA, ó là wọ́n sí meji meji, ó sì tẹ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn lọ, ṣugbọn kò la àdàbà ati ẹyẹlé náà.

11. Nígbà tí àwọn ẹyẹ tí wọ́n máa ń jẹ òkú ẹran rábàbà wá sí ibi tí Abramu to àwọn ẹran náà sí, ó lé wọn.

12. Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀.

13. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún.

14. Ṣugbọn n óo mú ìdájọ́ wá sórí orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóo sìn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, wọn yóo jáde kúrò níbẹ̀ pẹlu ọpọlọpọ dúkìá.

15. Ìwọ náà yóo dàgbà, o óo di arúgbó, ní ọjọ́ àtisùn rẹ, ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ ni o óo kú.

16. Atọmọdọmọ rẹ kẹrin ni yóo pada wá síhìn-ín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò tíì kún ojú òṣùnwọ̀n.”

17. Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ṣú, kòkò iná tí ó ń rú èéfín ati ìtùfù tí ń jò lálá kan kọjá láàrin àwọn ẹran tí Abramu tò sílẹ̀.

18. Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate,

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 15