Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 28:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ,ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka.

20. Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ,ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.

21. Ojuṣaaju kò dára,sibẹ oúnjẹ lè mú kí eniyan ṣe ohun tí kò tọ́.

22. Ahun a máa sáré ati ní ọrọ̀,láìmọ̀ pé òṣì ń bọ̀ wá ta òun.

23. Ẹni tí ó bá eniyan wí,yóo rí ojurere níkẹyìn,ju ẹni tí ń pọ́n eniyan lọ.

24. Ẹni tí ó ja ìyá tabi baba rẹ̀ lólè,tí ó ní, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”,ẹlẹgbẹ́ apanirun ni.

25. Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere.

26. Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀,ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là.

27. Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní,ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún.

28. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde,àwọn eniyan á sá pamọ́,ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 28