Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 25:18-28 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú.

19. Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro,dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́.

20. Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù,tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀,ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́.

21. Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ,bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.

22. Nípa bẹ́ẹ̀ o óo wa ẹ̀yinná lé e lórí,OLUWA yóo sì san ẹ̀san rere fún ọ.

23. Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá,bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni.

24. Ó sàn kí á máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.

25. Gẹ́gẹ́ bí omi tútù ti rí fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,ni ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè rí.

26. Olódodo tí ó fi ààyè sílẹ̀ fún eniyan burúkúdàbí odò tí omi rẹ̀ dàrútabi kànga tí a da ìdọ̀tí sí.

27. Kò dára kí eniyan lá oyin ní àlájù,bẹ́ẹ̀ ni kò dára kí eniyan máa wá iyì ní àwájù.

28. Ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu,dàbí ìlú tí ọ̀tá wọ̀,tí wọ́n sì wó odi rẹ̀ lulẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 25