Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 25:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Má máa lọ sílé aládùúgbò rẹ lemọ́lemọ́,kí ọ̀rọ̀ rẹ má baà sú u, kí ó sì kórìíra rẹ.

18. Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú.

19. Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro,dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́.

20. Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù,tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀,ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́.

21. Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ,bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.

22. Nípa bẹ́ẹ̀ o óo wa ẹ̀yinná lé e lórí,OLUWA yóo sì san ẹ̀san rere fún ọ.

23. Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá,bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni.

24. Ó sàn kí á máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.

25. Gẹ́gẹ́ bí omi tútù ti rí fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,ni ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè rí.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 25