Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 22:2-18 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.

3. Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́,ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà,ó sì kó sinu ìyọnu.

4. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.

5. Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn,ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn.

6. Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn,bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.

7. Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.

8. Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.

9. Olójú àánú yóo rí ibukun gbà,nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.

10. Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀,asọ̀ ati èébú yóo sì dópin.

11. Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́,tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́.

12. Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́,ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po.

13. Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta!Yóo pa mí jẹ lójú pópó!”

14. Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá,ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀.

15. Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde,ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde.

16. Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ,tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.

17. Tẹ́tí rẹ sílẹ̀ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n,kí o sì fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ mi,

18. nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ,tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 22