Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 22:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ,kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ.

2. Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.

3. Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́,ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà,ó sì kó sinu ìyọnu.

4. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.

5. Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn,ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn.

6. Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn,bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.

7. Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.

8. Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.

9. Olójú àánú yóo rí ibukun gbà,nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 22