Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 8:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ta ló dàbí ọlọ́gbọ́n? Ta ló sì mọ ìtumọ̀ nǹkan? Ọgbọ́n ní ń mú kí ojú ọlọ́gbọ́n máa dán, á mú kí ó tújúká kí ó gbàgbé ìṣòro.

2. Pa òfin ọba mọ́, má sì fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọrun.

3. Tètè kúrò níwájú ọba, má sì pẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń di ibinu, nítorí pé ohun tí ó bá wù ú ló lè ṣe.

4. Nítorí pé ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé. Bí ọba bá ṣe nǹkan, ta ló tó yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò?

5. Ẹni tí ó bá ń pa òfin mọ́ kò ní rí ibi; ọlọ́gbọ́n mọ àkókò ati ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà ṣe nǹkan.

6. Gbogbo nǹkan ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wahala wọ ẹ̀dá lọ́rùn.

7. Ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la; ta ló lè sọ fún eniyan bí yóo ṣe ṣẹlẹ̀?

8. Kò sí ẹni tí ó lágbára láti dá ẹ̀mí dúró, tabi láti yí ọjọ́ ikú pada, gbèsè ni ikú, kò sí ẹni tí kò ní san án; ìwà ibi àwọn tí ń ṣe ibi kò sì le gbà wọ́n sílẹ̀.

9. Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti ṣàkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé, mo rí i pé ọpọlọpọ eniyan ní ń lo agbára wọn lórí àwọn ẹlòmíràn sí ìpalára ara wọn.

10. Mo rí àwọn ẹni ibi tí a sin sí ibojì. Nígbà ayé wọn, wọn a ti máa ṣe wọlé-wọ̀de ní ibi mímọ́, àwọn eniyan a sì máa yìn wọ́n, ní ìlú tí wọn tí ń ṣe ibi. Asán ni èyí pẹlu.

11. Nítorí pé wọn kì í tètè dá ẹjọ́ àwọn ẹni ibi, ni ọkàn ọmọ eniyan fi kún fún ìwà ibi.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 8