orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo tún rí nǹkankan tí ó burú nílé ayé. Ó sì wọ ọmọ eniyan lọ́rùn pupọ.

2. Ẹni tí Ọlọrun fún ní ọrọ̀, ohun ìní ati iyì, tí ó ní ohun gbogbo tí ó fẹ́; sibẹsibẹ Ọlọrun kò jẹ́ kí ó gbádùn rẹ̀, ṣugbọn àjèjì ni ó ń gbádùn rẹ̀. Asán ni èyí, ìpọ́njú ńlá sì ni.

3. Bí ẹnìkan bá bí ọgọrun-un ọmọ, tí ó sì gbé ọpọlọpọ ọdún láyé, ṣugbọn tí kò gbádùn àwọn ohun tí ó dára láyé, tí wọn kò sì sin òkú rẹ̀, ọmọ tí a bí lókùú sàn jù ú lọ.

4. Nítorí òkúmọ yìí wá sinu asán, ó sì pada sinu òkùnkùn. Òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀, ẹnìkan kò sì ranti rẹ̀ mọ́.

5. Kò rí oòrùn rí, kò sì mọ nǹkankan, sibẹsibẹ ó ní ìsinmi; nítorí náà ó sàn ju ẹni tí ó bí ọgọrun-un ọmọ tí ó kú láìrí ẹni sin òkú rẹ̀ lọ.

6. Bí ó tilẹ̀ gbé ẹgbaa (2,000) ọdún láyé kí ó tó kú, tí kò sì gbádùn ohun rere kankan, ibìkan náà ni gbogbo wọn ń pada lọ.

7. Gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe, nítorí àtijẹun ni, sibẹsibẹ oúnjẹ kì í yó ni.

8. Kí ni anfaani tí ọlọ́gbọ́n ní tí ó fi ju òmùgọ̀ lọ? Kí sì ni anfaani tí talaka rí ninu pé ó mọ̀ ọ́n ṣe ní àwùjọ eniyan.

9. Ó sàn kí ojú ẹni rí nǹkan, ju kí á máa fi ọkàn lépa rẹ̀ lọ. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pẹlu.

10. Ohunkohun tí ó bá ti wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a sì ti mọ ẹ̀dá eniyan, pé eniyan kò lè bá ẹni tí ó lágbára jù ú lọ jà.

11. Asán a máa pọ̀ ninu ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀; kì í sì í ṣe eniyan ní anfaani.

12. Ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún eniyan láàrin ìgbà kúkúrú, tí kò ní ìtumọ̀, tí ó níí gbé láyé, àkókò tí ó dàbí òjìji tí ó ń kọjá lọ. Ta ló mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ láyé lẹ́yìn òun, lẹ́yìn tí ó bá ti kú tán?