Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 5:10-20 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu.

11. Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ.

12. Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru.

13. Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn.

14. Àdáwọ́lé wọn lè yí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè fi bẹ́ẹ̀ pàdánù ọrọ̀ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè rí nǹkankan fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.

15. Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé.

16. Nǹkan burúkú gan-an ni èyí pàápàá jẹ́; pé bí a ṣe wá bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe lọ. Tabi èrè wo ni ó wà ninu pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo làálàá wa láyé.

17. Ninu òkùnkùn, ati ìbànújẹ́ ni a ti ń lo ìgbésí ayé wa, pẹlu ọpọlọpọ ìyọnu, àìsàn ati ibinu.

18. Wò ó! Ohun tí mo rí pé ó dára jù, tí ó sì yẹ, ni pé kí eniyan jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn gbogbo làálàá tí ó ń ṣe láyé, ní ìwọ̀nba ọjọ́ tí Ọlọrun fún un, nítorí èyí ni ìpín rẹ̀.

19. Gbogbo ẹni tí Ọlọrun bá fún ní ọrọ̀ ati ohun ìní, ati agbára láti gbádùn wọn, ati láti gba ìpín rẹ̀ kí ó sì láyọ̀ ninu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni.

20. Kò ní ranti iye ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí pé, Ọlọrun ti fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 5