Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 45:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ìwọ̀n òróró gbọdọ̀ péye gẹ́gẹ́ bí ìlànà; ìdámẹ́wàá ìwọ̀n bati mẹ́wàá ni òṣùnwọ̀n bati kan ninu òṣùnwọ̀n kori kọ̀ọ̀kan òṣùnwọ̀n kori gẹ́gẹ́ bíi ti homeri.

15. Ẹ níláti ya aguntan kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ ninu agbo ẹran kọ̀ọ̀kan tí ó tó igba ẹran, ninu àwọn agbo ẹran ìdílé Israẹli. Ẹ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16. “Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ kó àwọn nǹkan ìrúbọ náà fún àwọn ọba Israẹli.

17. Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

18. OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ẹ pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ẹ fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ibi mímọ́.

19. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi sí ara òpó ìlẹ̀kùn tẹmpili, ati orígun mẹrẹẹrin pẹpẹ ati òpó ìlẹ̀kùn àbáwọlé gbọ̀ngàn ààrin ilé.

20. Bákan náà ni ẹ gbọdọ̀ ṣe ní ọjọ́ keje oṣù láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀; kí ẹ lè ṣe ètùtù fún tẹmpili.

21. “Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni, ẹ gbọdọ̀ ṣe ọdún Àjọ Ìrékọjá, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ óo máa jẹ fún ọjọ́ meje.

22. Ní ọjọ́ náà ọba yóo pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn ará ìlú.

23. Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

24. Fún ẹbọ ohun jíjẹ yóo pèsè òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati òṣùnwọ̀n hini òróró kọ̀ọ̀kan fún òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.

25. “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje, tíí ṣe ọjọ́ keje àjọ̀dún náà, yóo pèsè irú ẹbọ kan náà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 45