Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 44:28-31 BIBELI MIMỌ (BM)

28. “Wọn kò ní ní ilẹ̀ ìní nítorí èmi ni ìní wọn, ẹ kò ní pín ilẹ̀ fún wọn ní Israẹli, èmi ni ìpín wọn.

29. Àwọn ni wọn óo máa jẹ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àwọn ni wọ́n ni gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ ní Israẹli.

30. Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín.

31. Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀ tabi tí ẹranko burúkú bá pa, kì báà jẹ́ ẹyẹ tabi ẹranko.

Ka pipe ipin Isikiẹli 44