Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 42:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àwọn yàrá ti àgbékà kẹta kéré, nítorí ibùjókòó-òkè ti àgbékà kẹta fẹ̀ ju àwọn tí wọ́n wà níwájú àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti àgbékà ààrin lọ.

6. Àgbékà mẹta ni àwọn yàrá náà, ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára ògiri ní àjà kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì ní òpó bíi ti gbọ̀ngàn ìta, nítorí náà ni wọ́n ṣe sún àwọn yàrá àgbékà òkè kẹta sinu ju ti àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti ààrin lọ.

7. Ògiri kan wà ní ìta tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ àwọn yàrá ní apá ti gbọ̀ngàn ìta, ó wà níwájú àwọn yàrá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25).

8. Àwọn yàrá ti gbọ̀ngàn ìta gùn ní aadọta igbọnwọ (mita 25), ṣugbọn àwọn tí wọ́n wà níwájú tẹmpili jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50).

9. Nísàlẹ̀ àwọn yàrá wọnyi, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn bí eniyan bá ti ń bọ̀ láti ibi gbọ̀ngàn ìta.

10. Bákan náà, àwọn yàrá kan wà ní ìhà gúsù, lára ògiri òòró àgbàlá ti ìta, wọ́n fara kan àgbàlá tẹmpili,

11. ọ̀nà wà níwájú wọn. Wọ́n rí bí àwọn yàrá ti ìhà àríwá, òòró ati ìbú wọn rí bákan náà. Bákan náà ni ẹnu ọ̀nà wọn rí, ati ìlẹ̀kùn wọn.

12. Nísàlẹ̀ àwọn yàrá ìhà gúsù, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn. Bí eniyan bá wọ àlàfo náà, ògiri kan dábùú rẹ̀ níwájú.

Ka pipe ipin Isikiẹli 42