Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 41:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ibi mímọ́, ó wọn àtẹ́rígbà rẹ̀, ìbú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 3).

2. Ìbú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ògiri ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà gùn ní igbọnwọ marun-un marun-un (mita 3), lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. Ó wọn ibi mímọ́ inú náà: òòró rẹ̀ jẹ́ ogoji igbọnwọ (mita 20), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 10).

3. Lẹ́yìn náà, ó wọ yàrá inú lọ, ó wọn àtẹ́rígbà ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 3), ògiri ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà sì gùn ní igbọnwọ meje (mita 3½).

4. Ó wọn òòró yàrá náà, ó jẹ́ ogún igbọnwọ, (mita 10), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 10), níwájú ibi mímọ́ náà. Ó sì wí fún mi pé ìhín ni ibi mímọ́ jùlọ.

5. Lẹ́yìn náà, ó wọn ògiri tẹmpili, ó nípọn ní igbọnwọ mẹfa (mita 3), ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ igbọnwọ mẹrin (bíi mita 2) yípo Tẹmpili náà.

6. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ alágbèékà mẹta, ọgbọ̀n yàrá ni ó sì wà ninu àgbékà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mọ òpó sí ara ògiri Tẹmpili yíká, kí wọn baà lè gba àwọn yàrá dúró kí ó má baà jẹ́ pé ògiri Tẹmpili ni óo gbé wọn ró.

7. Àwọn yàrá náà ń fẹ̀ sí i láti àgbékà dé àgbékà, bí òpó tí wọ́n mọ sí ara ògiri Tẹmpili ṣe ń tóbi sí i. Àtẹ̀gùn kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tẹmpili náà tí ó lọ sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àgbékà kinni, ó gba inú ti ààrin lọ sí èyí tí ó wà lókè patapata.

8. Mo rí i pé Tẹmpili náà ní pèpéle tí ó ga yíká. Ìpìlẹ̀ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ ọ̀pá kan tí ó gùn ní igbọnwọ gígùn mẹfa (mita 3).

9. Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½), apá kan pèpéle tí kò ní ohunkohun lórí jẹ́ igbọnwọ marun-un. Láàrin pèpéle Tẹmpili

10. ati àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ gbọ̀ngàn fẹ̀ ní ogún igbọnwọ (mita 10), yíká gbogbo ẹ̀gbẹ́ tẹmpili.

11. Àwọn ìlẹ̀kùn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ṣí sí apá pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀. Ìlẹ̀kùn kan kọjú sí ìhà àríwá, ekeji kọjú sí ìhà gúsù. Ìbú pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká.

12. Ilé tí ó kọjú sí àgbàlá Tẹmpili ní apá ìwọ̀ oòrùn fẹ̀ ní aadọrin igbọnwọ (mita 35), ògiri ilé náà nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká, òòró rẹ̀ sì jẹ́ aadọrun-un igbọnwọ (mita 45).

Ka pipe ipin Isikiẹli 41